factograf
YO
Sign in

Jenna Ortega

Jenna Ortega
All data from the card 3
Ọjọ́ìbí
Jenna Marie Ortega27 Oṣù Kẹ̀sán 2002Coachella Valley, California, U.S.
Iṣẹ́
Actress
Ìgbà iṣẹ́
2012–ìsinsìnyí

Jenna Marie Ortega tí a bí ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án ọdún 2002, jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nínú àwọn fíìmù láti ìgbà èwe rẹ̀, ó sì gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú eré Jane the Virgin (2014–2019). Ó gbajúmọ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó ṣe Harley Diaz nínú eré Disney kan, Stuck in the Middle (2016–2018), ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Imagen Award fún ipa rẹ̀ nínú fíìmù yìí. Ó tún kópa Ellie Alves nínú fíìmù You ní ọdún 2019 àti nínú fíìmù Yes Day (2021) tí Netflix ṣe.

Ortega kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù bi The Fallout (2021), Scream àti X (méjèèjì ní ọdún 2022), àti Scream VI ( ní ọdún 2023). Ní ọdún 2022, ó kópa Wednesday Addams nínú fíìmù Netflix tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Wednesday, èyí sì mú kí wọ́n yàn fún àwọn tí ó le gba àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe àti Screen Actors Guild Awards.

Ìpìlẹ̀

Wọ́n bí Jenna Marie Ortega ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án oṣù 2002,Coachella Valley ní California ni wọ́n bí sí, òun ni ọmọ kẹrin nínú mẹ́fà. Bàbá rẹ̀ wá láti Mexico, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Mexico àti Puerto Rica.

Read next

In 71 languages

Text from Wikipedia, CC BY-SA 4.0 · Source article