Abraham Lincoln (i; ni a bí ní Ọjọ́ kejìlá, Oṣù èrèlé, Ọdún 1809, ó sì kú ní Ọjọ́ karùndínlógún, Oṣù igbe, Ọdún 1865. Ó jẹ́ Ààrẹ kẹrìndínlógún Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó ṣèjọba láti Oṣù Ẹrẹ́nàn Ọdún 1861 títí di Oṣù Kẹrin Ọdún 1865 tí wọ́n sì paá sí orí ipò.
Lincoln jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè nígbà Ogun Abẹ́lé ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà —Ogun tó dá lórí ìtàjẹ̀sílẹ̀ ẹrú, òfin àti ìjìyàn òṣèlú. Nígbà ogun náà, ó dá ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè dúró, ó sì fi òpin sí òwò ẹrú ṣíṣe, ó fún ìjọba ní agbára, ó sì ṣí ojú-ọ̀nà sí ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè.
Ní ogun jíjà yìí ó dá ìṣọ̀kan sí, ó fi òpin sí òwò ẹrú ṣíṣe, fún ìjọba lágbára, ó sì jẹ́ kí ìlọsíwájí bá okòwò ìlú. Ni àsìkò ogun yìí náàni Lincoln pàdánù ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ti ìṣẹ̀lẹ̀ yìí si jẹ ohun ìbànújẹ́ fún un. Àmọ́ síbẹ̀síbẹ̀, kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn báa.
Wọ́n bíi ní Hodgenville, Kentucky, Lincoln dàgbà sí ìwọ̀ oòrùn frontier ní Kentucky àti Indiana. Ó kọ́ ara rẹ̀ ní ìwé, ó di agbẹjọ́rò ní Illinois, Olórí Ẹgbẹ́ Òṣèlú Whig àti ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti lllinois ní ibi tí ó ti lo ọdún méjìlá. Wọ́n yàn án sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti United States ní Ọdún 1846, Lincoln mú ìlọsíwájú ba okòwò látàrí ilé-ìfowópamọ́, owó orí ìṣòwò lókèèrè àti ọkọ̀ ojú irin.
Àwọn ìtọ́kasí
Ìwé ìtàn
- Burkhimer, Michael (2003). One Hundred Essential Lincoln Books. Cumberland House. ISBN 978-1-58182-369-1. https://archive.org/details/100essentiallinc0000burk.
- Foner, Eric (2008). Our Lincoln: New Perspectives on Lincoln and His World. W.W. Norton. ISBN 978-0-393-06756-9. https://archive.org/details/isbn_9780393067569.
- Holzer, Harold and Craig L. Symonds, eds. Exploring Lincoln: Great Historians Reappraise Our Greatest President (2015), essays by 16 scholars
- Manning, Chandra, "The Shifting Terrain of Attitudes toward Abraham Lincoln and Emancipation", Journal of the Abraham Lincoln Association, 34 (Winter 2013), 18–39.
- Smith, Adam I.P. "The 'Cult' of Abraham Lincoln and the Strange Survival of Liberal England in the Era of the World Wars", Twentieth Century British History, (Dec 2010) 21#4 pp. 486–509
- Spielberg, Steven; Goodwin, Doris Kearns; Kushner, Tony. "Mr. Lincoln Goes to Hollywood", Smithsonian (2012) 43#7 pp. 46–53.
