factograf
YO

Ìsọ̀gbẹ́dalẹ̀

Ìsọ̀gbẹ́dalẹ̀
Ìsọ̀gbẹ́dalẹ̀ tó ré kọjá ààlà ní Somalia
Ìsọ̀gbẹ́dalẹ̀ tó ré kọjá ààlà ní Somalia

Ìsọ̀gbẹ́dalẹ̀ jẹ́ irú ìbàjẹ́ eyi ti ń dé bá ilẹ̀ díẹ̀díẹ̀, tí ó ń sọ ilẹ̀ ọlọ́ràá di aṣálẹ̀ gbígbẹ nítorí àkópọ̀ àwọn ìlànà àdánidá àti àwọn ìgbòkègbodò ènìyàn.

Ohun tààrà tó ń fa ìsọ̀gbẹ́dalẹ̀ ni pípadánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewéko. Èyí jẹ́ àbájáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, bóyá lẹ́yọ-kọ̀ọ̀kan tàbí ní àkópọ̀, bíi ọ̀dá, ìyípadà ojú ọjọ́, oko ríro fún iṣẹ́ àgbẹ̀, ìjẹko jù, àti gígé igi lúlẹ̀ pípa igbó run fún igi dídáná tàbí àwọn ohun èlò ìkọ́lé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ewéko ń kó ipa pàtàkì nínú mímú kí a pinnu àwọn àkópọ̀ ohun ẹlẹ́mìí inú ilẹ̀, àwọn ìwádìí ti fihàn pé, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè, ìwọ̀n ìfọ́núlẹ̀ àti ìṣàn omi ń dínkù lopolopo pẹ̀lú bí agbègbè tí ewéko bò ṣe ń pọ̀ sí i. Àwọn ojú ilẹ̀ tó gbẹ láìní ààbò máa ń fẹ́ lọ pẹ̀lú afẹ́fẹ́ tàbí kí àkúnya omi gbá wọn lọ, èyí sì ń fi àwọn ipele ilẹ̀ ìsàlẹ̀ tí kò lọ́ràá sílẹ̀, tí ó ń yan nínú oòrùn, tí ó sì ń di pápatá ilẹ̀ líle tí kò le mú èso jáde.

Ó kéré tán, ìdá àádọ́rùn-ún àwọn olùgbé ilẹ̀ gbígbẹ ń gbé ní àwọn orílè-èdè tó ń gòkè àgbà, níbi tí wọ́n tún ń jìyà nítorí àwọn ipò ọrọ̀ ajé àti àwùjọ tí kò dára. Ilẹ̀ tó ń bàjẹ́ tún ń mú kí ipò yìí burú sí í nítorí ìdínkù nínú ìmújáde, àìfọwọ́sọ̀yà àwọn ipò ìgbésí ayé, àti ìṣòro láti ní àwọn ohun àlùmọ́nì àti àǹfààní.

Read next

In 74 languages

Text from Wikipedia, CC BY-SA 4.0 · Source article