factograf
YO
Sign in

Àṣà

Àṣà
Religion and expressive art are important aspects of human culture
Religion and expressive art are important aspects of human culture
Germans marching during a folk culture celebration
Germans marching during a folk culture celebration
The Acropolis of Athens
The Acropolis of Athens
Writings often create a sense of cultural identity, Ernest Hemingway writing
Writings often create a sense of cultural identity, Ernest Hemingway writing
4 images

Àdàkọ:CS1 config

Àṣà ( KUL-chər or KUUL-chər) jẹ́ àkójọpọ̀ ìmọ̀ tí ó kún fún ìhùwàsí àwùjọ, àwọn ilé-ìṣẹ́ (àjọ), àti àwọn àṣà ìlànà tí a rí nínú àwọn àwùjọ ènìyàn. Ó tún kó ìmọ̀, ìgbàgbọ́, ọ̀nà iṣẹ́ ọnà, òfin, àṣà, agbára, ìwà, àti àṣà ìṣe ojoojúmọ́ àwọn ẹni-kọọkan tí wọ́n wà nínú àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí jọ. Àṣà a sáábà máa jẹyọ láti inú orírun kan tàbí ibi kan ni pàtó.

Àwọn ènìyàn máa ń gba àṣà wọlé nípasẹ̀ àwọn ìlànà kíkẹ́kọ̀ọ́, pàápàá jùlọ ìkọ́ni sínú àṣà àti ìbáṣepọ̀ àwùjọ; èyí ni a fi ń rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn àṣà ní gbogbo àwùjọ. Àṣà ìlànà kan máa ń ṣàlàyé ìhùwàsí tí ó yẹ nínú àwùjọ; ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìtọná fún bí ènìyàn ṣe yẹ kí ó hù, bí ó ṣe yẹ kí ó wọ aṣọ, èdè tí ó yẹ kí ó lò, àti ìwà tí ó yẹ nínú ipo kan—ó sì di àpẹẹrẹ ohun tí a ń retí nínú ẹgbẹ́ àwùjọ kan. Gbigba àṣà kan ṣoṣo nínú ẹgbẹ́ àwùjọ lè mú ewu wá, gẹ́gẹ́ bí irú ẹ̀dá kan ṣoṣo ṣe lè rẹ̀ tàbí parun nígbà ayípadà ayíká, nítorí aini agbára láti fèsì dáadáa sí irú ayípadà bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, nínú àṣà ológun, akíkanjú Courage/valor ni a ka sí ìhùwàsí tí ó wọ́pọ̀ fún ẹni-kọọkan, àti pé ojúṣe, ọlá, àti ìṣòtítọ́ sí ẹgbẹ́ àwùjọ ni a ka sí ìwà rere tàbí ìfèsì tó yẹ nínú àkóso ìjà continuum of conflict. Nínú ẹ̀sìn, a tún lè rí àwọn ànímọ́ tí ó jọra bẹ́ẹ̀ nínú ẹgbẹ́ àwùjọ kan.

Ìyípadà àṣà (cultural change), tàbí ìtúnṣe ipò rẹ̀, ni ìtúnkó tàbí àtúnṣe ìmọ̀ àṣà kan nínú àwùjọ. Àwọn àṣà máa ń ní ipa láti inú ara wọn—àwọn agbára tí ń mú kí ayípadà wá àti àwọn tí ń dí ayípadà dúró. Àwọn àṣà tún máa ń ní ipa láti òde nípasẹ̀ ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn àwùjọ. Àwọn àjọ bíi UNESCO máa ń gbìmọ̀ láti pa àṣà mọ́ àti láti dáàbò bo àṣà cultural heritage.


Description

[[File:Africa_Speaks!_(1930)_-_Pygmy_Drummers.jpg|thumb|Pygmy musicwọn koko ro wípé ó jẹ́ ìfihàn àkọ́kọ́ ti orin púpọ̀-ohùn (polyphony) nínú orin àgbáyé, tí a ti kọ sílẹ̀ ó kere tán ọdún 200 kí ìmọ̀ yìí tó farahàn ní Yúróòpù. Àṣà ni a ka sí èrò pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀dá ènìyàn (anthropology), ó sì kún fún gbogbo àwọn ohun tí a ń kọ́ nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ àwùjọ nínú àwọn àwùjọ ènìyàn. Àwọn àfihàn àṣà tí gbogbo ènìyàn ní wà ní gbogbo àwùjọ. Àwọn wọ̀nyí ní àwọn ọ̀nà ìfarahàn bíi ọ̀nà iṣẹ́ ọnà, orin, ijó, àṣà ìṣe, ẹ̀sìn, àti àwọn ìmọ̀-ẹrọ bíi lílò irinṣẹ́, sísè oúnjẹ, ilé ààbò, àti aṣọ. Ìmọ̀ àṣà ohun-èlò ń tọ́ka sí àwọn ohun tí a lè fọwọ́ kàn gẹ́gẹ́ bí ìfarahàn àṣà, bíi ìmọ̀ ẹrọ, ilé-kíkó, àti iṣẹ́ ọnà. Ní àkókò kan náà, àwọn apá tí kì í ṣe ohun-èlò nínú àṣà—bíi ìlànà ètò àwùjọ (pẹ̀lú ètò ìṣèlú àti àwọn ilé-ìṣẹ́ àwùjọ), àròsọ, ìmòye, lítírésọ̀ (tí a kọ sílẹ̀ àti ti ẹnu), àti sáyẹ́ǹsì—ni wọ́n jọ jẹ́ ogún àṣà tí a kò lè fọwọ́ kàn ti àwùjọ kan.

Read next

In 220 languages

yoаԥсшәаAfrikaansAlemannischአማርኛaragonésالعربيةܐܪܡܝܐمصرىঅসমীয়াasturianuаварAymar aruazərbaycancaتۆرکجهбашҡортсаBasa BaliBoarischžemaitėškaBikol Centralбеларуская (тарашкевіца)беларускаяBetawiбългарскиभोजपुरीBislamaပအိုဝ်ႏဘာႏသာႏবাংলাབོད་ཡིགবিষ্ণুপ্রিয়া মণিপুরীbrezhonegbosanskiбуряадcatalà閩東語 / Mìng-dĕ̤ng-ngṳ̄CebuanoChamoruᏣᎳᎩکوردیcorsuqırımtatarcačeštinakaszëbscziчӑвашлаCymraegdanskdagbanliDeutschZazakiދިވެހިބަސްΕλληνικάemiliàn e rumagnòlEnglishEsperantoespañoleestieuskaraestremeñuفارسیsuomivõrofrançaisarpetanNordfriiskfurlanFryskGaeilgekriyòl gwiyannenGàidhliggalegoAvañe'ẽGaelgHausa客家語 / Hak-kâ-ngîHawaiʻiעבריתहिन्दीFiji HindihrvatskiKreyòl ayisyenmagyarհայերենinterlinguaBahasa IndonesiaInterlingueIgboIlokanoгӀалгӀайIdoíslenskamedžuslovjanskyitaliano日本語Patoisla .lojban.JawaქართულიQaraqalpaqshaTaqbaylitқазақшаភាសាខ្មែរಕನ್ನಡYerwa Kanuri한국어къарачай-малкъарکٲشُرkurdîkernowekкыргызчаLatinaLadinoLëtzebuergeschLingua Franca NovaLugandaLimburgsLigureLadinlombardລາວlietuviųlatviešuMadhurâमगहीBasa BanyumasanMalagasyолык марийMinangkabauмакедонскиമലയാളംмонголमराठीBahasa MelayuMaltiMirandésမြန်မာဘာသာэрзяньمازِرونیNapulitanoNedersaksiesPlattdüütschनेपालीनेपाल भाषाNederlandsnorsk nynorsknorskNovialisiNdebele seSewulaoccitanlivvinkarjalaOromooиронਪੰਜਾਬੀPapiamentuPälzischpolskiPiemontèisپنجابیپښتوportuguêsRuna Simiရခိုင်ikirundiromânăрусскийрусиньскыйसंस्कृतम्саха тылаsicilianuScotsسنڌيsrpskohrvatski / српскохрватскиසිංහලSimple EnglishslovenčinaسرائیکیslovenščinaanarâškielâchiShonaSoomaaligashqipсрпски / srpskiSiSwatiSeelterskSundasvenskaKiswahiliSakizayaதமிழ்తెలుగుтоҷикӣไทยTürkmençeTagalogtolışitoki ponaTürkçeXitsongaтатарча / tatarçaTwiئۇيغۇرچە / Uyghurcheукраїнськаاردوoʻzbekcha / ўзбекчаvènetovepsän kel’Tiếng ViệtVolapükwalonWinaray吴语isiXhosaმარგალურიייִדישVahcuenghZeêuws文言閩南語 / Bân-lâm-gí粵語中文isiZulu

Text from Wikipedia, CC BY-SA 4.0 · Source article